LYRICS

Tani mo gbekele ti mo fi n s’ayo
Tani mo gbekele ti mo fi n gbe’se mo ngbe
Tani mo gbekele ti mo fi n yan

Repeat

Adlib: Tani tani gan
Mo ń gbese mo ngbe

Igba eru ba mi sibe mo n s’ayo
(Mo ń s’ayo)
Igba eru ba mi sibe mo n gbe’se mo ngbe
(Mo n gbe’se mo ngbe)
Igba eru ba mi sibe mo n yan
Igbagbo ireti l’o mu mi n s’ayo
(Ayo ninu Baba mi)

Igbagbo ireti l’o mu mi n gbe’se mo ngbe
(Mo n tesiwaju oo)
Igbagbo ireti l’o mu mi n yan

Tani mo gbekele ti mo fi n s’ayo
Baba ni mo gbekele ti mo fi n gbe’se mo ngbe
Oun mo gbekele ti mo fi n yan

Igba eru ba mi sibe mo n s’ayo
(Nitori mo j’omo Baba)
Igba eru ba mi sibe mo n gbe’se mo ngbe
(Mo n gbe’se mo n tesiwaju l’ona naa)
Igba eru ba mi sibe mo n yan

Igbagbo ireti l’o mu mi n s’ayo
(Eni gbeke l’Oluwa kò ni j’ogun ofo)
Igbagbo ireti l’o mu mi n gbe’se mo ngbe
(B’ó ti le wu k’o ri mo n gbe’se mo ngbe)
Igbagbo ireti l’o mu mi n yan

Ninu igbekele aanu ti kii sa
Iyen lo mu mi de’bi o wa titilai
Aanu t’o bà t’o si wa ko le gbòn mi re, bi mi o ba ti jòó re o wa titilai

O wa titilai, o wa titilai
Aanu t’o ba t’o si wa ko le yìn mí nù, bi mi o ba ti joo re o wa titilai

Ore ofe ki n ma lo joo re ni mo nwa sii, ileri t’o se t’aa si maa se ko le ju mi le, aanu t’o mu mi de’bi
si wa ko le tan lailai, bi mi o ba ti joo re o wa titilai

O wa titilai o
O wa titilai
O wa kò le tan
O wa titilai
Aanu t’o ba t’o si wa ko le gbòn mí re lailailai, bi mi o ba ti joo re o wa titilai

Ìtònà ni mo gba ki n le maa s’ayo
Iranwo ni mo fe lati maa rin’na yi
Imole k’ó maa tan bi mo ti nlo

Ad lib: Ìtònà ni mo gba
Ìtònà ni mo bèbè fun o
Imole a maa tan
Ìtònà lat’oke wa
Ìtònà k’o wà fun mi l’ona mi
Lati maa rinna yi o

Ìtònà lat’oke wa
Igbekele mi wa ninu Baba oju ò le ti mi lailai
Mo n tesiwaju l’ona naa, mo ng’oke si l’ojojumo ni

Imole k’ó maa tan bi mo ti nlo

Iwaju iwaju l’òpa ebiti mi a maa re si o
Imole k’ó maa tan

Imole k’ó maa tan bi mo ti nlo.

TRANSLATION


Added by

admin

SHARE

WRITE A TRANSLATION OR SUGGEST CORRECTION FOR THIS LYRICS

ADVERTISEMENT