LYRICS

Interlude
Adákẹ́ dájọ́
Adákẹ́ dájọ́
Ò n ló mọ wá o, Ò ń wò wá w’ọkàn
Ohun gbogbo tí a gbáyé ṣe
Òun ló dá òjiji mọ́ wa ò
Ìpinlesẹ̀ ayé wa ooo, àt’opin rẹ̀, o rí gbogbo kọ̀rọ̀ (2x)
Ẹni tó dá ojú o, kòní s’àlaíríran
Olú tó dá etí o, kò le ṣ’alaígbọràn
Kòsí kọ̀rọ̀ lójú rẹ̀, gbangba kedere ló rí gbogbo wa

Chorus: Adákẹ́ dájọ́
Adákẹ́ dájọ́
Ò n ló mọ wá o, Ò ń wò wá w’ọkàn
Ohun gbogbo tí a gbáyé ṣe
Òun ló dá òjiji mọ́ wa ò
Ìpinlesẹ̀ ayé wa ooo, àt’opin rẹ̀, o rí gbogbo kọ̀rọ̀

Ka yé ṣ’ẹ̀sín, ka yé pe ńi ẹ̀sìn, ka lọ já’wọ́ pátá
A ò le gan Ọlọ́run pẹ̀lú ‘gbàgbọ́ ojú torí kòní lè gbà wá
A ń fi ti’pá gbọ́ràn sí ‘lànà ẹ̀sìn, òfin Ọlọ́run wa d’àfiẹ́yìn
Ọ̀pọ̀ dára lójú, ìwà wọn ò dọ́kàn
T’ẹ̀gbin tìdọ̀tí kò jẹ́ kádúrà ọ̀pọ̀ onígbàgbọ́ ó gbà
Òjijì t’Ẹlẹ́dà dá mọ́ wa, o ń ṣ’àfihàn ohun ìkọkọ̀ o
Ẹ ò ní lè gbà’bọdè f’Ọ́lọ́run, onítọ̀hún a wulẹ̀ tán ‘ra ẹ pa
Ọlọ́run aláwòpa, dákun má wò mí pa

Chorus: Adákẹ́ dájọ́
Adákẹ́ dájọ́
Ò n ló mọ wá o, Ò ń wò wá w’ọkàn
Ohun gbogbo tí a gbáyé ṣe
Òun ló dá òjiji mọ́ wa ò
Ìpinlesẹ̀ ayé wa ooo, àt’opin rẹ̀, o rí gbogbo kọ̀rọ̀

Eemọ̀ tó wo ‘jo Ọlọ́run ti wá búrẹ́kẹ́, gbogbo aye dì ‘ránṣẹ́ Ọlọ́run
Àt’ẹni Bàbá rán, àt’ẹni ebi lé dé
Wòlí ọ̀sán gangan, ìyẹn lọ bí rẹ́rẹ
Orí pẹpẹ di ‘gbalẹ̀ egúngún
At’álàfọ̀ṣẹ at’èlépè
Ògo ológo dẹ̀kú t’on mí wọ̀ s’agbára
Ìgbàdí ń bẹ lábẹ́ collar ọ̀pọ̀ wọn
Àwọn t’ógun ńjà t’on torí k’ógun o lè ṣẹ́ t’on wọ‘nú ìjọ wá
O ma ṣe arakun laṣọ gbagi lógun to ń kún ogun wọn
Abẹ́ ò rí ìjọ, kí Jésù tó dé kí ni yóò dà o

Chorus: Adákẹ́ dájọ́
Adákẹ́ dájọ́
Ò n ló mọ wá o, Ò ń wò wá w’ọkàn
Ohun gbogbo tí a gbáyé ṣe
Òun ló dá òjiji mọ́ wa ò
Ìpinlesẹ̀ ayé wa ooo, àt’opin rẹ̀, o rí gbogbo kọ̀rọ̀

Interlude
Ẹ jẹ́ ka bi ra wa léèrè, gbogbo ìranṣẹ́ Ọlọ́run pátá
Kíni ìdáhùn sí ìbéérè yí o
Ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run ti di ‘wàásù ìgbaanì lẹ́nu wa
Èrè wo loníṣòwò àgbà ń jẹ nínu iṣẹ́ wa
Ẹ gbọ́ èrè wo, èrè wo, l’Olúwa ń jẹ
A fọwọ́lẹ́rán o mà ń wò wá o
Kó ma kasé mi láì lerè Kankan

Interlude
Kí loo rò, kí loo sọ
Nígbà t’a ba p’orúko ọ àwọn ènìyàn
Ta ò ba pe ọ mọ́ ọmọ o
Kí loo rò, kí loo sọ
Kí loo rò, kí loo sọ
Nígbà t’a ba p’orúko ọ àwọn ènìyàn
Kí loo rò, kí loo sọ
T’a ba p’oruko ni’joba orun
T’a pe won titi ti o de kan e o
Ẹni to ń tọ́ka s’ọ́mọ àpaadì, àt’ẹyin tó mọ ‘mo ilé ológo
T’oń bá p’orúkọ ní’jọba ọ̀run, t’oń o ka mr census ẹ ki loo ro
Kí loo rò, kí loo sọ
Nígbà t’a ba p’orúko ọ àwọn ènìyàn
Tá o bá pè ọ mọ́ ọmọ o
Kí loo rò, kí loo sọ
Onígbàgbọ ka ri mi ètè èké
Láti inú ìjọ jẹ ‘ra wa lẹ́sẹ̀ dede
Àdúrà àt’aawè òdì s’ẹnikejì
Ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lóri pẹpẹ sí pẹpẹ
Ẹ ò rántí O da ọgbọn ó ju ọgbọn lọ
Ẹ ó ba lákọ bí ìbọn lẹ́sẹ-ò-gbejì
Kí loo rò, kí loo sọ
Nígbà t’a ba p’orúko ọ àwọn ènìyàn
Tá o bá pè ọ mọ́ ọmọ o
Kí loo rò, kí loo sọ
Ọjọ ńlá, Adájọ́ ayé fẹrẹ de
Àiyíwapadà ìdajọ́ a rò
K’óníkálukú lọ yẹ’ra ẹ̀ wò
Ibi t’o bá kù sí, gb’àdúrà k’o tún ṣe
Ko ma bà di kí loo rò
K’ẹ́nu ma wo ji, ailèsọ̀rọ̀
Kí loo rò, kí loo sọ
Nígbà t’a ba p’orúko ọ àwọn ènìyàn
Tá o bá pè ọ mọ́ ọmọ o
Kí loo rò, kí loo sọ
En eh eh eh eh eh mo wi t’èmi o, ọ̀rẹ́ ma di’tí
Mo ma di’na ọ̀run mo ‘ra ẹ, o ti ń f’àmi hàn, Jésù ò ní pẹ́ dé
Ẹrù igi to ń bẹ lójú rẹ, lọ gbe kúrò, ko yé tẹnubọlẹ̀ sọ̀rọ̀
Lọ ronu ko pa ìwà dà, ka si tọrọ fún àanú
K’a ju’wọ́ ju’sẹ̀ k’a túbá f’Ọ́lọ́run, k’a le ba jọba , ka lè kà wá mọ́ wọn
Iṣẹ́ wa láyé yi ni láti wá ìjọba Ọlọ́run
Lẹ́yìn rẹ̀, ohun tó kù, a ó fi fún wa
O ń bọ̀ láìpẹ́, ṣ’áṣàrò ayé rẹ
Iṣẹ́ wa láyé yì ni láti wá ìjọba Ọlọ́run
Lẹ́yìn rẹ̀, ohun tó kù, a ó fi fún wa
O ń bọ̀ láìpẹ́, ṣ’áṣàrò ayé rẹ
Iṣẹ́ wa láyé yì ni láti wá ìjọba Ọlọ́run
Lẹ́yìn rẹ̀, ohun tó kù, a ó fi fún wa
O n bo laipe, s’asaro aye re

TRANSLATION

Interlude
Silent judge
Silent judge
He knows us, he his watching us and our hearts
Everything we are doing on earth
He created a shadow with us
The foundation of our life and the end, he sees all that is hidden (2x)
The creator of the eyes would be able to see
The creator of the ear, would be able to ear
There is no hidden places to him, he sees everything clearly

Chorus: Silent judge
Silent judge
He knows us, he his watching us and our hearts
Everything we are doing on earth
He created a shadow with us
The foundation of our life and the end, he sees all that is hidden (2x)

We should stop our shameful acts that we call religion, and stop them totally
We cannot mock God with fake religion because he will not save us
We go by forceful religious doctrines and forget God’s laws
Many are a beauty to behold, but have ugly attitudes
Sin and dirty attitudes has rendered many believers prayers unanswerable
The shadow that the creator made with us is revealing hidden things
You cannot harbour evil for God, you would only deceive yourself to death
God that can stare at one to death, please don’t stare at me till I die

Chorus: Silent judge
Silent judge
He knows us, he his watching us and our hearts
Everything we are doing on earth
He created a shadow with us
The foundation of our life and the end, he sees all that is hidden (2x)

Everyone has suddenly become a prophet of God
The one sent by his father and the one hunger chased here
Prophets all of a sudden… uncountable
The alter has become a masquerade chamber
The one with incantations and curses
Another person’s glory suddenly becomes a masquerade regalia that is used to acquire strange powers
String of charms is hidden under most of their collars
People who are fighting battles that come into the church looking for victory
A pity, the prophets have more regalia of battles to add to their problems
Can’t you see the church, before Jesus comes, what would it be?

Chorus: Silent judge
Silent judge
He knows us, he his watching us and our hearts
Everything we are doing on earth
He created a shadow with us
The foundation of our life and the end, he sees all that is hidden (2x)

Interlude
Let us ask ourselves, all servants of God
What would be the answer to this question?
The sermon about heaven as become ancient to our tongues
What is the profit the master makes from our works?
Hear, what profit does our Lords gets?
He will put his hands on his cheeks and keep staring at us
He shouldn’t take me without any profits

Interlude
What will be your tale, what will you say
When they call the names of people
And you name is not among the children
What will be your tale, what will you say
When names of people are called
What will be your tale, what will you say
When names are called in the kingdom of heaven
And the names are called without yours
You who are pointing to the children of hell, and you who have be identified with the church of God
When names are called, and your name is not called
What will be your tale, what will you say
When names are called
And you are not called with the children
What will be your tale, what will you say
Fake Christian, back biter
From the church, we betray each other regularly
Evil prayers and fasting against your neighbours
Evil intimacy from one alter to another
You do not remember that he created wisdom surpassing wisdom
You will meet him ready at the end of the journey
What will be your tale, what will you say
When names are called
And your name is not called among the children
What would be your tale, what would you say,
On the great day, the judge of the world is almost here
Unchangeable judge of mornings
Let everyone check themselves
So it won’t be what you would say
So you won’t end up mute
What would your tell be, what would you say
When names are called
And your name is not called among the children
What would your tale be, what would you say
Eh eheheheheh I have said mine, my friend do not be deaf
Don’t block your road to heaven, the revelation is here, Jesus will soon arrive
Remove all burdens of sin and put a stop to gossips
Think and change your attitude, then ask for mercy
We should worship God with our whole being, so that we would reign with him, and be counted as a child
Our only job on earth is to seek the kingdom of God
After this, all what is left would be given to us
He is coming soon, think of your life
Our only job on earth is to seek the kingdom of God
After this, whatever is left would be given to us
He is coming soon, think of your life.



Added by

admin

SHARE

WRITE A TRANSLATION OR SUGGEST CORRECTION FOR THIS LYRICS

ADVERTISEMENT