LYRICS

Àwá ẹ̀dá tọ́ l’Ọ́run dá
Ayé oto tótó lawà (ayé tawà yatọ̀)
Oníkálukú ló yan àyànmọ́
Ayé àgbélèbú la wà
Oh oh oh ooo oh
Oh oh oh ooo oh
Àgbélèbú oh oh oh
Ẹ̀dá tó wá sílé ayé
Ka tó lè yọ̀ a ó sunkún o (A ó sunkún)
Ayé àgbélèbú l’awà
T’abá bímọ tuntun jòjòló
Tibi t’ọmọ ni yó kọ́wọ̀rín bọ̀ wá ayé
A kẹ́hìndé ọmọ alábàrín ọmọ
Ibi ṣà l’orúkọ rẹ̀ ń jẹ́
Ibi àti ríbi l’ẹ̀dá ò le sọ
Ìgbà ibi dé fún ẹ̀dá ò mọ̀ láyé
Èyí wa sàrí dájú o pé
Ẹ̀dá ti wáyé pẹ̀lú ogun náà

Chorus: Oh oh oh ooo oh
Oh oh oh ooo oh
Àgbelèbú oh oh oh
Ẹ̀dá tó wá sílé ayé
Ka tó lè yọ̀ a ó sunkún o
Ayé àgbélèbú lawá

Bá ti wáyé pẹ̀lú ibi
Bẹ̀ la wáyé pẹ̀lú àyànmọ́
Àpot́i ògo o bá wa wáyé
Kọ́kọ́rọ́ tí ò si o ń bẹ nínu àdánwò
Bí a bá sin ibi a kì ń sin ògo
Ògo ń fara sin sáyé ẹ̀dá gbogbo
Kátó lè yọ̀ a o ṣẹ́gun náà
Kọ́kọ́rọ ògo àìrí ni a gbọ́dọ̀ wá
Àwa ẹ̀dá tọ l’Ọ́run dá
Ayé ọ̀tọ̀ tọ̀tọ̀ la wá
Oníkálukú ló yan àyànmọ́
Ayé àgbélèbú la wá

Chorus:Oh oh oh ooo oh
Oh oh oh ooo oh
Àgbélèbú oh oh oh
Ẹ̀dá tó wá sílé ayé
Kató lè yọ̀ a ó sunkún o
Ayé àgbélèbú lawá

Sábàbí ni àgbélèbú jẹ́
Á má jásire fún àwọn tó bá lè gbe
Ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́ kìle gbé àgbélèbú
Wọ́n a ma bógun ayé wọn rojọ́ bí ọ̀rẹ́
Tásìkò ba ń kọjá lọ wọ́n ò ní fura
Jóbù kojú ìdanwò láyé
Kàkà kó fẹ jọ́ sẹ́ Ọlọ́run
Ó gbé àgbélèbú rẹ̀ láì wẹ̀hìn
Ìgbà tí ṣòro tán ẹwá wo àrà
Àrà ńlá t’Ọ́lọ́run fidá

Chorus: Oh oh oh ooo oh
Oh oh oh ooo oh
Àgbélèbú oh oh oh
Ẹ̀dá tó wá sílé ayé
Kató lè yọ̀ a ó sunkún o
Ayé àgbélèbú lawà

Aláìníbíre sọ àgbélèbú d’ẹrù
Wọ́n s’ogun ìgbà díẹ̀ d’ọba wọn
Wọ́n wá foríbalẹ̀ fun
Bí ìṣòro bá sì jọba láyé ẹ̀dá tán
O lè ṣebé peni ránṣẹ́ dandan oo
Irú wọn kìlé ro re mọ́ra wọn
Kódà wọ́n a tún sọ débi Ọlọ́run
Wọ́n a ma wá bí góngó orí imú adáni wáyé
Eh! tí wọ́n o f’ọwọ́ gún
Ìkà akún inú wọn
Wọ́n ò níle bóníre yọ̀
Iṣẹ́ wọn yì lo ń mú wọn gbáyé
Bí ẹni tí kò gbógo ayé rí rárá

Àwa ȩ̣̀dá t’Ọ́lọ́run da
Ayé ọ̀tọ̀tọ̀ lawá
Oníkálukú ló yan àyànmọ́
Ayé ọ̀tọ̀tọ̀ lawá

Chorus: Oh oh oh ooo oh
Oh oh oh ooo oh
Àgbélèbú oh oh oh
Ẹ̀dá tó wá sílé ayé
Ka tó lè yọ̀ a ó sunkun o
Ayé àgbélèbú lawá

Interlude
Aile gbadura
Àìgbọràn kúkurú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìkanjú ọkàn
O mú kí ọ̀tá yọ àsikò àgbélèbú
Láti gbẹ̀mí lẹ́nu ẹlòmíràn
Àwọn ọmọ ìsirelì sọ ìrìn àjò ogójì ọjọ́
Dogójì ọdún mọ́ra wọn lọ́wọ́
Ṣẹrí àfọwọ́fà àti àìnísùúrù
Àti àìka àgbélèbú kún ẹbọ pípé
Kòjẹ́ k’ẹ́lòmíràn o mọ ọ̀nà àti rìn débi ògo, ògo rẹ̀
Ìrirí ayé kòle tini pa jọ̀wọ́
Ńṣe lo ń fi ọgbọ́n pọ́n ẹ̀dá láyé
Ṣẹwá rí agídí, ọgbọ́n àgbọ́njù ènìyàn
A mú kí ẹlòmíràn maa wo àpotí ògo wọn lọ́ọkankán láìnílè débẹẹ̀
Ọlọ́run fi ilẹ̀ ìlerí han Mósè
Ṣùgbọ́n kò débẹ̀ ará
Ọlọ́run kìí da májẹ̀mú tóbá ẹnikẹ́ni dá
Bẹ́ni lábẹ́ àkóso bótilẹ́wù kórí o, Ọlọ́run jẹ́ olódodo

Chorus: Oh oh oh ooo oh
Oh oh oh ooo oh
Àgbélèbú oh oh oh
Ẹ̀dá tó wá sílé ayé
Ka tó lè yọ̀ a ó sunkun o
Ayé àgbélèbú lawá

Ènìyàn tóyẹ kóyọ ẹsẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan lẹ́kù
Wọ́n gbọ́nju wọ́n a gbẹ́sẹ̀ ní méjì-mejì
Wọ́n fẹ́ fò ní ọ̀nà àgbélèbú tiwọn
Ṣé ayé wọn gbojíkan fún ìfíra sàtánì
Ànáìnàtán owó ẹbọ, àìsàn apanikú sáyé
Ìpayà ílà ílo ọkàn
Ikú àìtọ́jọ́ wọ́n a lọ bíi rẹ́rẹ
Ọlá tí Ì kánjú dà wọ́n nìyẹn
Láìmọ̀pé kòsí àdánwò tí enìkan ò rírí
Àwọn tó kasí wọ́n ò rirí
Ẹnití kòrirí kòlèní ẹ̀rí
Májẹkí àgbélèbú sọ ẹ́ di aláìgbàgbọ́
Ńṣe lóyẹ kó fún ọ lágbára
Nítórí yóò fi àsirí ìkọkọ̀ han ní
Àti báoṣe tó láyé, bá o ṣe fẹ̀ tó láyé
Àní baóṣe tó láyé, ba o ṣe rógo lò tó láyé

Interlude
Ọ̀rọ̀ ògo ó dọwọ́ aṣẹ̀dá
Àyàfi ka bẹ Ọlọ́run
Àgbélèbú dandan àgbélèbú
Kamole kató gbe (2x)
Ẹnití ò le ṣàkóso ọkàn rẹ̀
Kòní lè gbé àgbélèbú dèbi ògo
Kótó di ẹni afọ̀kantàn a ó yẹ̀ ọ́ wò
Inú olóúnjẹ kòní pẹ́ tán
Olùgbalà náà gbé ti ẹ̀ rí o
Kótó gbadé ògo ojúbọ̀rọ̀ kọ́
Ọ̀nà àgbélèbú jási kòtò jásí gegele
Bóti ń gbe o koma gbàdurà
Másiye mejì komába ṣe lásán
Má jowu ́ògo ológo láìda
kóma ba jìyà siyà bóti ko
gbe gbe tẹ̀lé Olùgbalà
Orúkọ Jésù ló wólé ogun
call: orúkọ Jésù
response: ilé ìṣọ́ agbára
call: olódodo sáwò ibẹ̀
response: Ó si rí ìyè
call: Gbé àgbélèbú rẹ
response: Ẹbọ rẹ ni
call: Fìgbàgbọ́ gbe o
response: Gba gbogbo ẹ̀ sáyọ̀
call: Ó fẹ́rẹ̀ débẹ̀́ náà
response: Ó dámilójú
call: kílomọ̀ tó jẹ́ àgbélèbú rẹ
response: ohunkóhun lóléjẹ́ o fẹ́rẹ̀
call: àgbélèbú àtètè gbe àtètè debẹ̀
response: adáni wáyé ń woso ki (bẹẹni, bẹẹni)
call: Hánà gbé tirẹ̀ tẹ̀gàn tomijé kóíbímọ o
response: àwọn ọmọ ísírelì gbe tiwọn pẹ̀lẹgbàn kóídélẹ̀ ìlerí
call: Rútù gbé àgbélèbú pẹ̀lú ìkorò ará ẹ gbọ́
response: o kúkú gbe tán o lárin to ko gbe
call: ìran Rútù lati bí Jésù Olúwa wa o
response: bórí báti mọ o lo ṣe ń fọ́ olóri (bẹẹni)
call: Ológo ńlá, orúkọ kẹ̀ǹkẹ̀
response: Ẹlẹ́dà ń wọmọ adámọ̀́ bóti rí
call: Bóbá ti fún ẹ sáájú o lè mámọ̀ lò
Ábráhámù jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ojú lásán kọ́
Jósẹ́fù o fojú bọ̀rọ̀ dépò kójá lamba
Igbeleni le ni ja sipo kòtò ṣe rere
K’Ẹ́stérì to daya ‘ba o ti sìnlú rí o
Má retí eni tí ó ràn ọ tí o bá ń gbe lọ́wọ́
Àgbélèbú, àdágbé àjọsọ o
Júju layé wà k’Ọ́lọ́run tó pe ìmọ́lẹ̀
Ọ̀nà àgbélèbú aginjú ẹ̀rù ni
Tobá mú ramúramù máma wẹhìn o
Kòsẹ́ni tí ò nígbe àfalaìlógo
Gbe pẹ̀lú ìgboyà, wa tó débẹ̀
Amúni pàdé, pàdé, pàdé
Amúni pàdé angẹlì abánisé
Àwa ẹ̀dá t’Ọ́lọ́run dá
Ayé ọ̀tọ̀tọ̀ lawá
Oníkálukú ló yan àyànmọ́
Ayé ọ̀tọ̀tọ̀ lawá

Chorus: Oh oh oh ooo oh
Oh oh oh ooo oh
Àgbélèbú oh oh oh
Ẹ̀dá tó wá sílé ayé
Ka tó lè yọ̀ a ó sunkun o
Ayé àgbélèbú lawá

Lágbára, bàbá o
lágbára, bàbá ọ̀run
Àwa yóò débi ògo lọkọ̀ọ̀kan
ìbí wa kòní kùn wá o
lágbára ògo àrí wa
àpotí ògo á ṣèṣe (ẹ májẹ̀ n gbàgbé nígbà kọ̀ọ̀kan)
Èmi ni o jerè ògo
Àmín o, a délé
Látònílọ ẹ má wẹ̀hìn
Ẹni to ń sinmi, ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́mi
Kẹ́yin tó jagun ṣẹ́gun, ẹ ó borí
Lágbára, bàbá o
lágbára, bàbá ọ̀run
ogún rere ṣáni ìpín wa

TRANSLATION

We beings that God created
We are in a different world
Everyone chose a destiny
We come to the world with our cross
Oh ohooo oh
Oh ohohooo oh
The cross oh ohoh
We humans that came to earth
Be we show up, we cry (we cry)
We come to the world with our cross
When we have a new born
The child comes with a placenta to earth
The twin of the child, the one who journeys with the child
It is called evil
When human meet with this evil, we cannot tell
When evil will meet a man, we do not know on earth
This just confirms that
Humans come to the world with his battle

Chorus: oh ohohooo oh
Oh ohohooo oh
The cross oh ohoh
Humans that came to the world
Before we show up we cry
We come to the world with our cross

As we come to the world with evil
That’s how we came with our destiny
We came with a stool of glory
The key to open it is in tribulations
When there is no evil, there isn’t glory
Glory hides in every human
Before it is revealed we need to conquer our battles
We humans created by God
We came into the world differently
Each person chose a destiny
We came into the world with our own cross


Chorus: oh ohohooo oh
Oh ohohooo oh
The cross oh ohoh
Humans that came to the world
Before we show up we cry
We come to the world with our cross

The cross is like an opportunity
It could be a blessing to those who could carry it
A gossip usually cannot carry a cross
They talk to their battles like a friend
When times is far spent, they will not notice
Job faced tribulations in life
Instead of him to offend God with his words
He carried his cross without turning back
When the tribulations ended beauty came upon him
The mighty works God used his life for

Chorus: oh ohohooo oh
Oh ohohooo oh
The cross oh ohoh
Humans that came to the world
Before we show up we cry
We come to the world with our cross

The one without a course sees the cross like a heavy burden
they turn a little battle to their king
They bow before it
When a problem becomes king is a man’s life
It can send someone on a compulsory errand
Someone like that don’t think good of themselves
In fact, they would make it God’s fault
They would start asking the creator’s nose
While pointing fingers
They would be filled with wickedness
They won’t rejoice with the joyous
This deed makes them live on earth
Like one who has not carried the glory of the world at all


We humans created by God
We came into the world differently
Each person chose a destiny
We came into the world with our own cross

Chorus: oh ohohooo oh
Oh ohohooo oh
The cross oh ohoh
Humans that came to the world
Before we show up we cry
We come to the world with our cross

Interlude
Not being able to pray
Little disobedience and impatience of the heart
Makes the enemy rejoice during tribulations
To take life away from an individual
The children of Israel turned the journey of forty days
To forty years themselves
You see personal misconduct and impatience
And not counting the cross as a sacrifice
Makes an individual miss his way to his glory
Life challenges cannot push you off completely
It adds to your wisdom on earth
You see stubbornness and canniness
Makes an individual stare at his stool of glory from afar without reaching it
God showed Moses the promise land
But he didn’t get there
God doesn’t betray the covenant he made with anyone
Under any circumstances, God is faithful

Chorus: oh ohohooo oh
Oh ohohooo oh
The cross oh ohoh
Humans that came to the world
Before we show up we cry
We come to the world with our cross

Someone who is supposed to take steps one after the other
They count themselves wise and take two steps at a time
The want to fly in the direction of their own cross
Their life is easy prey for Satan
Spending endlessly on sacrifices, diseases that kill while living
Unrest less mind
They die young in numbers
That’s the wealth that impatience grants them
Without knowing there is no tribulation that is new
It becomes new to them that go through such
Some that has been through it, see it has an experience
Do not let your cross make you an unbeliever
It should make you strong
Because it will reveal hidden secrets
And how great you are to be, how big you are to be on earth
How great you are to be, how you will make use of your glory on earth

Interlude
Manifestation of our glory is in God’s hands
We need to beg God
The cross is a must. A must
We should see the light before we carry it (2x)
One who cannot take charge of his heart
Will not be able to carry his cross to his glory
Before you can be trustworthy, you will be tried
Food is for the stomach and all will end soon
The saviour carried his cross too
Before he was crowned with glory, it wasn’t an easy task
The road to the cross is filled with many pot holes and dangers
As you carry it, you need to keep praying
Don’t doubt so it won’t be in vain
Don’t harbour evil envy against another’s glory
So as not to add to your suffering
Carry it and follow the saviour
The name of Jesus can destroy the battle house
Call: the name of Jesus
Response: a strong tower
Call: the righteous runs into it
Response: and he is saved
Call: carry your cross
Response: it is your sacrifice
Call: carry it with faith
Response: count it all joy
Call: you are almost there
Response: I am certain
Call: what do you know is your cross?
Response: it could be anything at all
Call: carry your cross on time, so you will get to your destination on time
Response: the creator looks after you
Call: Hannah carried hers with shame tears before having a child
Response: the Israelites carried theirs with shame before reaching the promise land
Call: Ruth carried hers with bitterness, brethren hear me
Response: she carried it to the end
Call: through the descendant Ruth was Jesus our Lord born
Response:how great one would be determines one’s challenges
Call: the glorious, with a mighty name
Response: the creator looks at how the children of Adam are
Call: if he had given you earlier, you might not know how to make good use of it
Abraham was God’s friend, not just physically
Joseph didn’t get to his position easily
You could be chased into a pit before you succeed
Before Esther became a queen she served her nation
Don’t expect a helper when carrying it
The cross, is carried alone
The earth was dark before God called out light
The journey of the cross is the wilderness of fear
When it frightens, don’t look back
There is no one who won’t carry, only those with no glory
Be brave while living, you will soon get there
One would meet (3x)
One would meet an angel of help

Chorus: oh ohohooo oh
Oh ohohooo oh
The cross oh ohoh
Humans that came to the world
Before we show up we cry
We come to the world with our cross

By the power of our father
By the power of our heavenly father
We will all get to our place of glory
Evil will not be our portion
By the power, glory would see us
The stool of glory would open for us
I will inherit glory
Amen, we will reach our destination
From today, don’t look back
You who is resting, listen to me
Before you fight at all, you will conquer
By the power of our father
By the power of our heavenly father
We have a blessed inheritance



Added by

admin

SHARE

WRITE A TRANSLATION OR SUGGEST CORRECTION FOR THIS LYRICS

ADVERTISEMENT