LYRICS

Instrumentals

Àmín Áṣẹ ìdá a lamọ̀ o
Ẹni tí ò ni a pàdánù
Ìbà o tótó olú ìmọ̀ o
Ẹni tí ò ní ọ, kòní ǹkankan o
(Àmin aṣẹ̀dá)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
(oooooo)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
(Ẹ kòní ǹkankan o)

Mo wárí f’Ọ́ba to ní dídá aye eeee
Ìbà rẹ màré e, oní gbẹ̀dẹ̀ ọ̀run
Ìwọ to ní gbogbo ayé ní ìkawọ́
Bó ti dòyì kátó
Ìbà onímọ̀ tó ga jù ee
Baba ni bàbá ṣe

(Àmín áṣẹ ìdá mo gbébà fún)
Àmín áṣẹ ìdá la mọ o
(Ẹni tí ò ní ọ kẹ)
Ẹni tí ò ní a pàdánù
(Àdánù ńlá ló pa láyé, l’ọ́run)
Ìbà o tótó Olú ìmọ̀
(A ton ton to, mo rí bà, morí bà o)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan
(kòní ǹkankan)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
(E mà ní penre lábọ́)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
(Kòní kiní kan l’ágbọ̀n)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
(ooooooo)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan
(E kọ̀ní ǹkankan o)

Mo wárí f’Ọ́ba tóni dídá ayé eeee
Ìbà rẹ màré e, oní gbẹ̀dẹ̀ ọ̀run
Ìwọ toní gbogbo ayé ní ìkawọ́
Bóti dòyì kátó
Ìbà onímọ̀ tó gajù ee
Bàbá ni baba ṣe

(Àmín áṣẹ ìdá mo gbébà fun)
Àmín áṣẹ ìdá la mọ̀ o
(Ẹni tí ò ní ọ kẹ̀)
Ẹni tí ò ni a pàdánù
(Àdánù ńlá ló pa l’áyé, l’ọ́run)
Ìbà o tótó Olú ìmọ̀
(A tó tó tó, mo ríbà, mo ríbà o)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
(E mà ní pẹ̀rẹ̀ lábọ́)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
(Kòní kini ǹkan l’ágbọ̀n)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
(Ó tán fun láyé lọ́run o)
Ẹni tí ò ní ọ (ee)
Kòní ǹkankan

Ó dá òkun, ó dá ọ̀sà
Alárà to fi omi ṣe ọ̀ṣọ́
Ìwọ to mọ ibi ẹja gbà dódò
Májẹ̀mú tó buyọ̀ já òkun
Iyanrìn tẹ̀ ká ayé
Ó dá òkùnkùn birimù
Ọ̀gá ìmọ́lẹ̀ oo
Ojú ọ̀run ò ní ìlẹkùn oo
Ó gbébi méjèèjì, láìrin ìrìn àjò
O mú ẹ̀dá gba inú ẹ̀dá wáyé
Ibi ẹ̀mí ń gbà lọ ba, ẹni kan ò mọ̀
Ajùlọ o ẹni tí ó wa o
Kòle mọ ǹkankan
(ẹni tí o wa kẹ̀ o)

Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
(kòri ǹkankan oo)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
(Afọ́jú sàn ju onítọ̀ún lọ mo gbà)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan
(ee)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan
(ee)

Májẹ̀mú àlàìlepin n lo jẹ́
Ìjìnlẹ̀ àlàìlètunwò
Ìràwọ̀ ń yọ láéláé lo ńkà (bẹ́ẹ̀ni)
Oṣùpá ǹṣe atọ́kùn tó bá dalẹ́ (bẹ́ẹ̀ni)
Ibi gbogbo la n ti mi ri (bẹ́ẹ̀ni)
O tún lọ fàràdá ọ̀run sáyé (bẹ́ẹ̀ni)
Ó ṣe òjò o tún sọ̀dá ẹ̀rùn (bẹ́ẹ̀ni)
Oṣùwọ̀n bí ọyẹ́, ó tún ṣòtútù (bẹ́ẹ̀ni o)
Ẹranko igbó wọ́n lọ súà (bẹ́ẹ̀ni)
Ewéko, ewébẹ̀ igi ìyẹn o ṣe ṣàwarí ná

Ẹni tí o ri ṣẹ́ ẹ, kòrí ǹkankan o
(Ẹni tí o ní ọ, kòní ǹkan)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan
(kódà kòrí ra ẹ̀ pa bẹ́ni)
Ẹni tí ò ríṣẹ́ ẹ, kòrí ǹkankan…

Instrumental….

Ó ṣemí dàbí òun, O pín mi ní ìpín
Tí kò jọ ti ẹ̀ni kejì
Mi o la lẹ̀ hù, èmi ni àmì aṣẹ̀dá l’átọ̀run
Àdágbẹ̀yìn ni mi ó wá fi mí j’Ọba
Ó dámí o fún mi ni re
Èmi ni bẹ́ẹ̀ni, àṣẹ Olódùmare ni
Àmin l’Òun, èmi lámí
Àyànmọ́ ògo, ogún mi ni
Ẹ̀da èmi lo fi ṣe ránṣẹ́ mi
Akòrí ìran mi, ojú ògo rẹ̀ ni
Mo ní ìmíyè rẹ̀ nínú

Ẹni tí o rí mí, kòrí ǹkankan
Eee, ẹni tí ò rí mí
Kòrí ǹkankan.
Ẹni ti o ri mi
Kòrí iṣẹ́ Ọlọ́run o
E (Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan)
Ẹni tí ò ri mí
Kòrí ǹkankan o
(e ó fójú)
Ẹni tí ò rí mí, kòríṣẹ́ Ọlọ́run wo
(Kòrí Olódùmarè, Ó dá mi bí òun ni)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan
Ẹni tí ò rí mi, kòríṣẹ́ Ọlọ́run wo
(oooooo)
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan o
Ẹni tí ò rí mí, kòríṣẹ́ Ọlọ́run wò
Ẹni tí ò ní ọ, kòni nkankan

Àmì làwa jẹ́, sí ìwọ àmín
Bẹ́ẹ̀ni ire lójẹ́ si aye wa o
Ọlọ́run làmín
Àmín lo n fàmín wa hàn
Ayé, àtọ̀run làmín yẹn ò
Aṣẹ̀dá ni àmín
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló jẹ́kí a ma wà
Ọlọ́run làmín
Àmín, àmín, àmín, àmín o

TRANSLATION


Added by

admin

SHARE

WRITE A TRANSLATION OR SUGGEST CORRECTION FOR THIS LYRICS

ADVERTISEMENT