LYRICS

Chorus: Ẹ̀rù ògò Rẹ bàmí
Ẹ̀rù ògò Rẹ bàmí o
Ẹlení ògo
Onítẹ̀ ògo
Aládé ògo
Ọlọ́lá inú ògo
Ẹlẹ́wà ògo
Kìkìdá ògo ògo
Akọ́dà ògo ògo
Ògo ninú ògo
Aṣájú ògo
Ìgbẹ̀yìn ògo
Ẹ̀rù ògo Rẹ bàmí o (2x)

(1) Bó ti ń gbé nínu ògo
O ń s’ògo lórí ìtẹ o
Ògo ló wọ̀ l’áṣọ
Olójú ògo ni
Ẹ̀dá ọ̀run f’ògo fún àràmandà ògo tó yí wọ́n ka
Bàbá ológó jùlọ tó dá ohun gbogbo pẹ̀lú ògo.
Chorus: Ẹ̀ru ògo rẹ bàmí, abbl

(2) Bóti lẹ́rùníyì tó
Ìtẹ́ ìdajọ́ taanú t’ògo
Ògo ọ̀tun ìṣẹjú sí ìṣẹjú
Ẹ̀wà tí ò lákàwé
Nígbogbo ìgbà sígbà
Òdòdo l’ògo Rẹ
Àwọn orílẹ èdè gbogbo ń ṣọlá lórí ògò Rẹ
Chorus: Ẹ̀ru ògo rẹ bàmí, abbl

(3) Ọlọ́run tó ta sánmọ̀ pẹ̀lú ògo
Ìwọ laṣajú ológo tó lẹ́rù níyì ìbà bàbá ìbà
Call: Alágolẹ́rù
Response: tólokè
Call: ẹlẹ́rùníyì
Response: tónílé
Call: onílé ọlá
Response: aládé ògo
Call: ó fi kìkìdá ògo
Response: ṣagbeji ara
Call: ògo ẹlẹ́rù
Response: ológo gbańlá
Jehófà Ọba, ológo
Jehófà jírèh ayé ayé mi ń wárí ògo Rẹ.
Call: Ẹ ma bámi gbé o, Ọlọ́run tó j’Ọlọ́run lọ
Response: Ẹ ma bámi gbe, Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run

Interlude
Call: Ẹ ma bámi gbe, Ọlọ́run ayérayé
Response: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run
Call: Ẹ bámi gbe, Ọlọ́run a tóbijù
Response: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, Ọlọ́run ológo jùlo
Call: Ẹ bámi gbe, ẹnitó sọ̀run òhun ayé ró
Response: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run
Call: Ẹ bámi gbe, Ọlọ́run àìborí o
Response: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, òun náà lólógo jùlọ
Call: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, Olúwa àwọn Olúwa
Response: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run
Call: Ẹ ma bámi gbega Ọlọ́run tíkì dòjú tini
Response: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, òun náà kì dójú tini
Call: Ẹ bámi gbe, òun náà kòmà jáni kulẹ̀ rí
Reponse: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run
Call: Ẹ mà bámi gbe Ọlọ́run tí kìi dalẹ̀
Response: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, òun náà lólógo jùlọ
Call: Asọ̀rọ̀ pàṣẹ ni o tíkìi sọ̀rọ̀ nù
Reponse: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, òun náà lólógo jùlọ
Call: Agbọmọlà ni tíkìi gbọmọ pa
Reponse: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run
Call: Ọrẹ mi ma lo jẹ́ o, kó dẹ̀ bọ́ta mi ṣọ̀rẹ́ o
Response: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, òun náà lólógo jùlọ
Call: Ẹ jọwọ́ ẹ bámi gbe ga, ọ̀rọ̀ tí ẹ náà á dayọ̀
Response: Ẹ bámi gbe, ẹ bámi gbe, Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run

Interlude
Call: Ọba kan wà o
Response: Ọba, Ọba (3x)
Kábíyèsí Ọba tótó (Ọba tótó)
Olórí ayé, kọ́kọ́rọ́ ayé
Ológùn àjọbọ (Kábíyèsì)
Kábíyèsì, Ọba tótó tótó

Ọba l’ọba tí ń f’ọba jẹ
Alágbàlá ire, a wúre
Adánikán jọba, adánikán gorí oyè
Kòdẹ̀ sẹ́ni tólèrò láé
Ọba ti ń gba ìdọ̀bálẹ̀ ọba
Onírùkẹ̀rẹ̀ iná, ọlọ́pà ògo
Ọba totijẹ kọrun àtayé tówà
Ọba ti ikú ò nílé kan láéláé
Call: Ọba kan wá ò
Response: Ọba, Ọba (4x)
Kábíyèsí Ọba tótó (kábíyèsí o)
Olórí ayé, kọ́kọ́rọ́ ayé
Ológùn àjọbọ (Kábíyèsí)

Kábíyèsí, Ọba tótó tótó
Ọba tótipẹ́ lóyè tí ò sì gbó
Ọba tẹ́nikẹ́ni o fi jẹ
Onídà iná tí ò ṣé fọwọ́pa
Ìtẹ́ rẹ̀ níbi tówà kòle si láé
Ọba ìgbaanì, Ọba ìgbà tuntun
Ọba ayé wọn ki i ju aare lọ
Ọba ti kìiṣe ẹgbẹ́ àarẹ àgbayé o
Ọba t’òle o’ọba, Ọba t’òle yiri ọba
Call: Ọba kàn wà o
Response: Ọba, Ọba (4x)
Kàbíyèsí Ọba tótó
Oló̰rí ayé, kọ́kọ́rọ́ ayé
Ológùn àjọbọ (Kábìyèsí)
Kábìyèsí, Ọba tótó tótó
Ọba to fi kún ọdun ọba láyé
Ọba ti ń gbẹ́jọ́, Ọba tí ń dájọ́
Ọba ti yóò ṣe ìdajọ́ àarẹ gbogbo
Ató bẹ̀rù, a bẹ̀rù gan an
Ọba tí gbogbo ayé yóò jíyìn fún gbẹ̀hìn
Ọba ti gbogbo ayé lo ń j’Ọba lé lórí
Ọba òkè yii, Ọba ìlẹ̀ gbogbo
Moṣe kábíyèsí rẹ o Ọba tóótóó
Call: Ọba kàn wà o
Response: Ọba, Ọba (4x)
Kàbíyèsí Ọba tótó
Oló̰rí ayé, kọ́kọ́rọ́ ayé
Ológùn àjọbọ (Kábìyèsí)

Kábìyèsí, Ọba tótó tótó
Moṣe kábíyèsí (kábio o sí)
Kábíoosí o, olórí ayé pátá
Ọlánlá tẹ́rẹre káríayé
Oní kọ́kọ́rọ́ ayé lọ́wọ́, kábióosí
(Kábíesí ní ẹ bá n ṣe)
Reponse: Kábíyesí
Call: Kábíyesí o
Response: kábióosí
Call: Your royal majesty, your excellency
Response: kábióosí
Kábiesí
Ìwọ lo kó gbogbo ayé jọ
kábióosí o, Ọba tótó
Ìwọ tóni kọ́kọ́rọ́ ayé lọ́wọ́, mo forí balẹ̀
kábióosí
Call: Ẹ ba n ké kábiesí
Response: kábiesí
Call: Gbogbo ayé ẹ wá rìrì
Response: kábiosí
Call: Ẹ sọpé o fọba lórí ọba

TRANSLATION

Chorus: I’m in awe of your glory
I’m in awe of your glory
You who own the mat of glory
You who own the throne of glory
You who own the crown of glory
You own the wealth in glory
You own the beauty in glory
So much glorious Glory
The creator of glory! Glory
The glory in glory
The beginning of glory
The end of glory
I’m in awe of your glory (2x)

(1) As you dwell in glory
You rule in glory on the throne
You are clothe in glory
Your eyes are of glory
Heavenly beings give glory to the mysterious glory that they surround
The father with enormous glory that created all with glory
Chorus: I’m in awe of your glory (2x)

(2) Full of fearful honour
The throne of judgement filled with mercy and glory
New glory minutes after minutes
Unfathomable beauty
Every time, from time to time
Your glory is the truth
Nations bask in the riches of your glory
Chorus: I’m in awe of your glory (2x)

(3) The God of heavens that tied the clouds with glory
You are the beginning of glory that is filled so much praise! Honour to you O Lord Honour
Call: the bell carrier
Response: that owns the heavens
Call: the one with fearful honour
Response: that owns the earth
Call: the owner of the wealthy house
Response: crowned with glory
Call: uses enormous glory
Response: to cover his whole body
Call: fearful glory
Response: huge glory
Jehovah King of glory
Jehovah Jireh my life trembles at your glory
Call: help me lift him up, God a0lmighty
Response: help me lift him up God of all gods

Interlude
Call:help me lift him up, ancient God
Response: help me lift him up, uplift him, Almighty God
Call: help me lift him up, the highest God
Response: help me lift him up, uplift him, God with surpassing glory
Call: help me lift him up, the one who holds both heaven and earth
Response: help me lift him up, uplift him, Almighty God
Call: help me lift him up, the undefeated God
Response: help me lift him up, he owns the highest glory
Call: help me lift him up, uplift him, Lord of lords
Response: help me lift him up, uplift him, Almighty God
Call: help me lift him up, uplift him, God who never disappoints a person
Response: help me lift him up, uplift him, he never disappoints
Call: help me lift him up, He has never failed a person
Response: help me lift him up, uplift him, Almighty God
Call: help me lift him up, God that never betrays
Response: help me lift him up, uplift him, he owns the highest glory
Call: The one who speaks with authority
Response: help me lift him up, uplift him, he owns the highest glory
Call: The one who saves a child and doesn’t kill a child
Response: help me lift him up, uplift him, God Almighty
Call: he is my friend and is not friends with my enemies
Response: help me lift him up, uplift him, he owns the highest glory
Call: please help me lift him up, you shall also be joyous
Response: help me lift him up, uplift him, God Almighty

Interlude
Call: there is a King
Response: He is king king (3x)
Unquestionable Able God (able God)
King of the earth, key of the earth
The one we worship together (unquestionable)
Unquestionable able king

He is a king who crowns other kings
The one with a hall of goodness
He alone is king, He alone sits on the throne
No one can dethrone him forever
The king who receives the adoration of other kings
The owner of the tassel of fire and the sceptre of glory
The king who has been before the creation of heaven and earth
The king who death can never touch forever
Call: there is a king
Response: He is king king (4x)
Unquestionable able God (unquestionable)
The King of the earth, key of the earth
The one we worship together (unquestionable)

Unquestionable able God
The king who has stayed long on the throne and he is worthy
The king who was crowned by no one
The one who has a sword of fire that cannot be caressed
Your throne is forever
Ancient king, modern king
The king of the earth is not more than a president
This king is incomparable to the president of earth
The King that can turn the head of a king
Call: the is a king
Response: king! King
Unquestionable able king
The King of the earth, key of the earth
The one we worship together (unquestionable)
Unquestionable able God
The king who adds to the years of a king on earth
The king who hears cases, the kings who judges
The king who would judge all presidents
The one who is to be feared, the feared king
The king who the whole world will report to at the end of days
The king who is king of all the world
The king of the heavens, the king of all earth
I say you are unquestionable, able God
Call: the is a king
Response: king! King
Unquestionable able king
The King of the earth, key of the earth
The one we worship together (unquestionable)

Unquestionable able God
I say you are unquestionable (unquestionable)
Unquestionable the head of all earth
The one with wealth that covers all earth
The one who holds the key to the earth
(Say he is unquestionable)
Response: unquestionable
Call: unquestionable
Response: you are unquestionable
Call: your royal majesty, your Excellency
Response: unquestionable
Unquestionable
You assembled the whole earth
Unquestionable able God
You who hold the key to the world, I bow before you
Unquestionable
Call: help me shout unquestionable
Response: unquestionable
Call: let the whole earth tremble
Response: unquestionable
Call: say he puts a king over other kings…



Added by

admin

SHARE

WRITE A TRANSLATION OR SUGGEST CORRECTION FOR THIS LYRICS

ADVERTISEMENT