LYRICS

Instrumentals

Halleluyah ni ń o maa kọ
Halleluyah, sí ìwọ Ọlọ́run mi
Orin halleluya, ni n o báwọn t’ọ̀run kọ
Halleluyah (halleluyah) ni n o maa kọ (ni n o maa kọ)
Halleluyah, sí ìwọ Ọlọ́run mi
Orin halleluyah, ni ń o báwọn t’ọ̀run kọ

Ojú ọ̀run fún dẹ́dẹ́
Àwọsánmọ̀ ní pele-ni-pele
Ẹ̀rù lófi kọ́ ayé
Òkun fún àjàrà
Ẹ̀da o yanbo àwọ̀
Ìwọ ló dá wa lárà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Mo kọrin halleluyah s’íwọ t’àwọn t’ọ̀run ńbọ
Halleluyah ni n o maa kọ
Halleluyah, sị́ ìwọ Ọlọ́run mi
Orin halleluyah, ni ń o báwọn t’ọ̀run kọ
Mímọ́ mímọ́ ni wọ́n ké
Àwọn t’ẹ̀dá ọ̀run, áńgẹ́lì lọ́wọ́ lọ̀wọ́
Wọ́n fi ọjọọjọ́ fi orí balẹ̀ o
Àgbàgbà ńké mímọ́
S‘Ólùdáńdè ayé gbogbo
Halleluyah si oní’tẹ̀ ògo àdììtú
Gbọgbọọrọ ọwọ́ tó na ayé já láti inú ọ̀run wá, kíkọrin wọn ò dàkẹ́ rí
Sí Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun
Halleluyah (si Ọlọ́run) ni n o maa kọ
Halleluyah (ee) síwọ Ọlọ́run mi (síwọ ẹlẹ́da mi)
Orin halleluyah (síwọ Ọlọ́run mi) ni n o b’àwọn t’ọ̀run kọ (bẹ́ẹ̀ni)

Halleluyah (eeya) ni n o maa kọ (ni n o ma kọ)
Halleluyah (lorin mi yóò jẹ́) síwọ Ọlọ́run mi (lọ̀rọ̀ mi yóò jẹ́)
Orin halleluyah ni n o báwọn t’ọ̀run kọ
Halleluyah ni wọn ńkọ

Wọ́n ṣẹ́gun ayé
Kòsí ìdàrúdàpọ̀ ohun gbogbo ńlọ létòletò
Ebi kò pawọn rí, bẹ́ẹ̀ lara kò niwọn rí
Kíkídà ayo, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlaafíà ní ìtẹ́ ògo
Àwa tàle ké halleluyah nínu ayé
Àwa lafi orin ìṣẹ́gun ṣe wá lógo
A ó jẹrí ọ̀tá, wọn a dẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀ pátá
Orin halleluyah laó tun fibá Jésù jọba, awa tagbàlà

Halleluyah, ni ń o maa kọ
Halleluyah, sí ìwọ Ọlọ́run mi
Orin halleluyah, ni n o báwọn tọ̀run kọ
Halleluyah (orin ọ̀run ni, orin ọ̀run ni, orin ìṣẹ́gun) ni n o maa kọ
Halleluyah, sí ìwọ Ọlọ́run mi (ẹ orin ìgbàlà ni)
Orin halleluyah, (ẹ jẹ́ kajọ kọ́) ni n o báwọn tọ̀run kọ

Sí Ọlọ́run láéláé, halleluyah ooo sí ẹni to ń bẹ lórí ìtẹ́ o
Halleluyah (halleluyah) sí ẹni tó lógo pátápirá
Ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin (bẹ́ẹ̀ni) sí ẹni tódá ayé àtọ̀run tó ṣáájú dé gbàdà bẹ̀hìn wò
Halleluyah oooooo, halleluyah oooo lorin mi
halleluyah oooo lorin mi
Orin mi (bẹ́ẹ̀ni) lorin mi yóò majẹ́, yóò jẹ́ o
Halleluyah, yóò maa jẹ́ lọ́sàn lóru o oooo
Halleluyah, Halleluyah, Halleluyah, Halleluyah (orin halleluyah)

TRANSLATION


Added by

admin

SHARE

WRITE A TRANSLATION OR SUGGEST CORRECTION FOR THIS LYRICS

ADVERTISEMENT