LYRICS

Instrumental

Mo ṣọpẹ́, ọkàn mi balẹ̀
Mo ṣọpẹ́, mo yìn ọ lógo ooo
Mo ṣọpẹ́, ọkàn mi balẹ̀
Ará tùmí o, Olúwa ṣeun

Instrumental

Ará tùmí, ọ̀kan mí balẹ̀
Mo dúpẹ́ gbẹdẹ lo rọ mi o
Tẹlẹ́ri òṣùka mi ga
Ẹ̀rù mí pọ̀, mo rìnà títí láì débuté
Ilẹ̀ ń ṣú, ilẹ̀ ń mọ, àjò mi ò yẹ̀nà
Mo ṣọpẹ́, ọkàn mi balẹ̀
Mo ṣọpẹ́, mo yìn ọ lógo ooo

Mo ṣọpẹ́, ọkàn mí balẹ̀
Ará tùmí o, Olúwa ṣeun
Mo dúpẹ́, o fara tùmí gbẹ̀dẹ̀
Oorùn ayé tani, af’ara ẹni koná
Ẹ̀dá ayé fẹ̀yìn sini, pàdà wá sọni lókò
Ọlọ́run ni ò jẹ́ kọ́gà aye gbaṣọ lọ́rùn mi o
Mo ṣọpẹ́, ọkàn mí balẹ̀
Mo ṣọpẹ́, mo yìn ọ lógo ooo (mo fìyìn f’Élédùmarè)

Mo ṣọpẹ́, ọ̀kàn mí balẹ̀ (Ọ̀kàn mi balẹ̀, gbẹ̀dẹ̀ lara tù mí̱)
Ara tùmí o Olúwa ṣeun
Mo dúpẹ́, o fara tùmí gbẹ̀dẹ̀
Oorùn aye tani, a fara ẹni koná
Ẹ̀da ayé fẹ̀yìn sini padà wa sọní lókò
Ọlọ́run ni ò jẹ́ kọ́gà aye gbaṣọ lọ́rùn mi o (O ṣé olóore)
Mo ṣọpẹ́, ọkàn mí balẹ̀ (Mo ṣọpẹ́, ọkàn mí balẹ̀)
Mo ṣọpẹ́, mo yìn ọ lógo ooo (Pẹ̀lẹ́ tu ni mo ń sin’Lọ́hun)

Mo ṣọpẹ́, (Gbẹ̀dẹ̀ ni mo ń sin bàbá) ọkàn mí balẹ̀ (ọkàn mi balẹ̀)
Ara tùmí o Olúwa ṣeun (Mo tẹ̀lé alájàó tó rọrùn)
Mi o sa ìlá ílo, mo dúpẹ́
Mi ò rìn pákánleke, mo ṣọpẹ́
Ò jẹ ń ma wáun tí ò sọnù kiri
Mo yin ọ́ ooo
Ò jẹ́ ń jókò láyè ènìyàn
Ò jẹ́ n lépa ẹ̀dá ẹgbẹ́ mi
Gbẹ̀dẹ̀ lọ̀rọ̀ mi, ẹ ní sáre mi a sáré kú
Mo ṣọpẹ́, ọkàn mí balẹ̀ (Ò jẹ ń malépa ẹ̀mí ẹgbẹ́ mi)
Mo ṣọpẹ́, mo yìn ọ́ lógo ooo (O jẹ́ ń joyé aboró nínú bí ọká)

Mo ṣọpẹ́, (O ṣé o) ọkàn mí balẹ̀ (ọkàn àìbalẹ̀, ikú lo ń sáré lé)
Ara tùmí o Olúwa ṣeun

Instrumental

Aládé àlááfíà
Ó tóbi
Alájàgà tó rọrùn, o pọ̀ o (ó mà pọ̀ o)
Ẹrù rẹ sì fúyẹ́ gẹngẹ
Ó ga ju ayé lọ (ó ga ju ayé lọ)
Olúwa mí ga ju ayé lọ o, ó tóbi
Ó tóbi (ó tóbi), ó pọ̀ o
Olúwa mí ga ju ayé lọ ò, ó tóbi
Ó tóbi (ó tóbi), ó pọ̀ o (ó mà pọ̀)
Olúwa mí ga ju ayé lọ ò, ó tóbi

TRANSLATION


Added by

admin

SHARE

WRITE A TRANSLATION OR SUGGEST CORRECTION FOR THIS LYRICS

ADVERTISEMENT