LYRICS

Ọlọ́run ni yóò majẹ́ (2x)
Lánà, lónì, lọ́la o, títí dé ayérayé
Ọlọ́run ni yóò majẹ́
Ọlọ́run ni yóò majẹ́ (2x)
(títí láé, títí láé, títí láé)
Lánà, lónì, lọ́la o, títí dé ayérayé (lóní o)
Ọlọ́run ni yóò majẹ́ (títí ayé)

Alágbára ni kòṣé ṣẹ́gun o
Ipá ńlá ni kòdẹ̀ lè pin o
Àìlèyípadà, tólayé ní ìkawọ́
Èmi ṣèbà olùdá ọ̀run o
(Èmi ṣèbà olùdá ọ̀run o)

Ọlọ́run ni yóò majẹ́
(Àkọ́kọ́ ń dá, olú ń dá ayé)
Ọlọ́run ni yóò majẹ́
(pátápirá ògo níbi tó parí sí)
Lánà, lónì, lọ́la o (pátápátá pirá ọlá), títí dé ayérayé (tópin sí)
Ọlọ́run ni yóò majẹ́

Àìlè tún wá ó ti wà kótó dá ọ̀run
Tẹ̀lẹ̀rí ni àti títí lónì
Ẹni nígbà tí o ní ìbẹ̀rẹ̀
Bẹ́ẹ̀ni kò lópin
Mo júbà akọ́dá ayé o
Pátápátá ògo

Ọlọ́run ni yóò majẹ́
(ẹni ládé tóti dádé kató dáyé)
Ọlọ́run ni yóò majẹ́
Ẹni ládé tóti dádé kató dá ọ̀run
Lánà lónì lọ́la o (ìṣajú ayé), títí dé ayérayé (aṣájú ọ̀run)
Ọlọ́run ni yóò majẹ́

Instrumentals

Kòsẹ́ni tó dá nígbà tó ti ń jọba o
A ò tọwọ́ ẹ̀dá kan hun adé orí ẹ
Àkọbi ọ̀run o, olùṣájú ayé dé
Jèhófà, èmí ṣè bá ọ
Ọ̀gangan ojú àwọn àgbàgbà mẹ́rìnlelógún

Ọlọ́run ni yóò majẹ́
(ìrijú ogun àwọn áńgẹ́lì ojoojúmọ́)
Ọlọ́run ni yóò majẹ́
(ìbà ẹni táwọn tọ̀run ń ṣe tí wọn ò dákẹ́)
Kòsí àríyanjìyan (pátápátá ògo) lórìgun mẹ́rin ọ̀run àtayé
Kòní ṣàìjẹ́ Ọlọ́run mọ́
Ọlọ́run ni yóò majẹ́ (ìwọ nìkan loma jẹ́ Ọlọ́run)
Ọlọ́run ni yóò majẹ́ (o ti ń jẹ́ Ọlọ́run kótó dá ọ̀run rárá)
Kòsí àríyanjìyan lórígun mẹ́rin ọ̀run àtayé
Kòní ṣàìjẹ́ Ọĺrun mọ́
Ọlọ́run ni yóò majẹ́ (èmi ṣèbà ọ̀rọ̀ kótán àṣirí ayé)
Ọlọ́run ni yóò majẹ́ (àṣirí ayé pẹ̀lú ọ̀run ọwọ́ rẹ nìkan lówà)
Lánà lónì lọ́la o (ìdá òṣùpá, ìdá ọ̀run) títí dé ayérayé
Ọlọ́run ni yóò majẹ́

TRANSLATION


Added by

admin

SHARE

WRITE A TRANSLATION OR SUGGEST CORRECTION FOR THIS LYRICS

ADVERTISEMENT