LYRICS

Instrumental

Hmhmmmm, oooo, eeee

You are worthy (3x)
Of my praise
You are worthy (3x)
Of my praise

Ẹlẹ́bùrú ìké oooo
Ò rán’mọ níṣẹ́ f’àyàti oooo
Aráni bánilọ ooooo
You are worthy
Ọba tó gbà mí la o
Ọlọ́wọ́ iná oooo
Ìwọ nìkan lògo yẹ ooo
You are worthy

You are worthy (You are worthy)
Ìwọ lóni ìyìn àt’ọla (You are worthy)
Bí moṣe de mo wá fi fún ọ (You are worthy)
Ẹlẹ́mì inú mi, bàbá (of my praise)
Bàbá àwọn bàbá
Lion of the tribe of Juda
King in his majesty
Ruler of the universe
I tremble at your feet

Lion of the tribe of Judea
Kinging in his majesty
Ruler of the universe
Worthy of our worship
Ìwọ tó jọba lórí gbogbo ayé (You are worthy)
Ìsọ́ ayé, ìṣọ́ ẹ̀mí ẹ̀dá gbogbo (response: You are worthy)
Olórí áńgélì, olórí ọ̀run (response: You are worthy)
Ìwọ to ń darí ayé àti ọ̀run pọ̀ (response: of my praise)
Ìwọ to dá ọ̀run to díjú rí (response: You are worthy)
Kọndọki ọ̀rọ̀ tódáyé àtọ̀run (response: You are worthy)
Ipá ńlá gbogbo ayé (response: You are worthy)
Òkè àti ilẹ̀ ẹ̀mí ọ̀run (response: Of my praise)
Ki gbogbo ọlá, ọlọ́lá tó ga jùlọ
Ọlọ́rọ̀ tó pọ̀ jùlọ
Ológo tó gajù
You are worthy
Ọba tó ju gbogbo ọba lọ
Ìjọba níbi gbogbo, olórí ayé
Ìsàlẹ̀ ilẹ̀
Aláínípẹ̀kun.

Aláínípẹ̀kun ni ọ́. (You are worthy)
Baba mẹ́talọ̀kan (You are worthy)
Ajùlọ to ń bẹ níbi gbogbo ẹ̀dá èèyàn (You are worthy)
Ará ọ̀run wọ́n ri (of my praise)
Aráyé rí ọ, tì’sàlẹ̀ ilè wọ́n mọ̀ ọ da (You are worthy)
Àmọ̀dájú ẹ̀dá gbogbo (You are worthy)
Nínú ẹ̀mí at’ara lati mọ̀ ọ́ (You are worthy)
Tafiri pé ìwọ nìkan l’ọpẹ́ yẹ o (of my praise)

Gbà o o
Ó f’ọ̀run nìkan ṣe kìkìdá wúrà
Ọ̀ dá ọ̀run pẹ̀lú ara ọ̀tọ̀
Ẹbọ mi àjísà, àjítọ́lá
Mo gbòṣùbà f’ógo ràm̀bàdẹ̀
Ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ ògo àrín ògo
Olúnkángun ìgbẹ̀yìn ògo
Ẹniti gbogbo ayé yòó pàdà wá bọ
Kábíèsí oooo
Moṣe kábíèsí o
Arayé k’Ọ́ba ní kábíèsì
Wọ́n ní kádé pẹ́ lórí kí bàtà pẹ́ lẹ́sẹ̀ o (bẹ́ẹ̀ni)
Ìwọ nìkan ni kábíèsí
Tá ò gbọ̀dọ̀ sọ pé kádé pẹ́ lórí fún
Èèwọ̀, a ò gbọ̀dọ̀ pé kí bàtà pẹ́ lẹsẹ̀ láéláè
Ṣádé tá ò mọ̀ gbà tódé sórí ẹ̀
Ṣé bàtà tá ò mọ̀ gbà tó wẹ̀sẹ̀ rẹ̀
(Alágbara gíga) T’áńgeẹ́lì gan ò mọ̀ (Bẹ́ẹ̀ni wọ̀n ò mọ́)
Gbogbo àwọn t’ọ̀run ń júbà ọ (Wọ́n ń júbà)
Ìwọ nìkan ni wọn ń bọ ò, mo báwọn bọ ọ́
Kíló wá ṣemí ṣayé mi, kíni ń o ṣe tí ń ò ní maa bọ ọ?
Láyé fábàdà kí n mári,
Gba ògo àtọla,́ gbá o
Gba ògo àtìyìn, gbá o
Ìwọ nìkan ló tọ́sí
You alone at worthy Lord
Gba ògo àtọla, gba ògo àtìyìn
Ìwọ nìkan ló tọ́sí
Àgádángòdo, ẹ̀mí gbogbo èèyàn
(Gba ògo àtọlá) ẹni tó lẹ̀mí (gba ògo àtọlá, gba ògo àtiyìn)
Ọ̀pàkan wòkan yè (ìwọ nìkan ló tọ́sí)

Ọba ti ń gẹṣin lóri eléniyàn ẹ̀dá gbogbo, pátápirá ọlá, ìwọ nìkan ló tọ́sí
Mo ni ara ọ̀tọ̀ (ìwọ nìkan ló tọ́sí) eeee gbá ooo (ìwọ nìkan ló tọ́sí)
Ẹlẹ́mì inú ẹ̀dá gbogbo (gba ògo àtọlá, gba ògo àtìyìn, ìwọ nìkan ló tọ́sí)
Ẹni tó f’ẹ̀mí ẹ̀ rúbọ f’èmi aa (gba ògo àtọla) gba o (gba ògo àtìyìn) gbá ògo
(ìwo nìkan ló tọ́sí) tani n bátún fi fún, gba gbogbo ògo, ò ní bẹ́nikẹ́ni pin
Ìwọ nìkan ló tọ́sí (you are worthy) o worthy (you are worthy) o worthy (you are worthy)
Ìwọ t’áńgẹ́lì ń bọ lọ́jọjọ́, àgbàgbà mẹ́rinlélógún ṣí adé kalẹ̀ (you are worthy)
Wọ́n bọ ìwọ nìkan torí ìwọ nìkan ló tọ́sí (you are worthy) ee ẹ̀da gbogbo ti ń bẹ nísàlẹ̀ ilè, ìwọ nìkan ni wọn dọ̀bálẹ̀ (of my praise)

Bẹ́ẹ̀ lo ń tuntun si lójojúmọ́ (you are worthy)
Bẹ́ẹ̀ lo ń yàtọ̀si nínu ògo ìkẹ́ (you are worthy)
Ìkẹ́ ológo to ń dán gbinrin (you are worthy)
Ògo tó bí ògo, tódá ògo, tó pọ́n ògo (of my praise)
Ìwọ nìkan ló worthy o
Mo gbọ́lá fún ọ, mo fìyìn fún ọ, mo fògo fún ọ, mo darapọ̀ mọ́ àwọn tọ̀run láti sọ wí pé o ṣé
Torí o worthy

TRANSLATION


Added by

admin

SHARE

WRITE A TRANSLATION OR SUGGEST CORRECTION FOR THIS LYRICS

ADVERTISEMENT